Ìkíni jẹ́ àṣà pàtàkì ninú àwọn àṣà Yorùbá.
Iwọ̀nyìí ní díẹ̀ ninú ìkíni àtìgbàdéìgbà ní ilẹ̀ Yorùbá:-
| |
Ìkíni |
Ìdáhùn |
| Ti a bá fẹ́ ki ẹni ni tí ó fẹ́ wọlé |
Àgò onilé o! |
Àgó yà o |
| Ti a bá fẹ́ ki ẹni ni ti ó dúró |
Ẹ kú idúró |
O! Ẹ kú àbọ̀ o |
| Ti a bá fẹ́ ki àlejò tí o bá ni ní ipàdé |
Àjọ kó tú o |
Ẹ máa wolẹ̀ |
| Ti a bá fẹ́ ki ẹni tí ń jẹ́un |
Mo mọ̀ọ́n rìn
tàbí
Mo báa yin re |
Àṣẹ o, ẹ sún mọhìn-in kí á jọ jẹun |
| Ti a bá fẹ́ ki àgbalagbà |
Àjinde ara yóò máa jẹ́ |
Iwọ náà yóò dàgbà |
| Ti a bá fẹ́ ki ẹni tí a tún pàdé lẹhìn ibẹ̀wò |
Ẹ kú idide ọjọ́ |
Kò t’ọ́pẹ́ |
| Ti a bá fẹ́ ki ènìyàn tí ó ń bá ṣe ayẹyẹ tàbí àyẹ́sí |
Ẹ kú ọrọ̀ ènìyàn
tàbí
Ẹ kú ífẹ́ |
Àwa nùun tàbí àmín |
| Ti a bá fẹ́ ki ní àsìkò ọyẹ̀ |
Ẹ kú ọyẹ̀ |
Gágá l’ará yá |
| Ti a bá fẹ́ ki ènìyàn ní àsìkò wàhálà |
Ẹ kú làásìgbò |
Ẹkú ọrọ̀ ènìyàn |
| Ti a bá fẹ́ ki ẹni ni tí ó jókòó |
Ẹ kú ìkàlẹ̀ |
|
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yii, ilé iṣẹ́ (tẹlifíṣàn) móhùn-máwòrán “Multichoice” láti orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà (South Africa) gbé ẹ̀ka titun jáde ní èdè Yorùbá ti wọn pe ní “Africa Magic Yorùbá”
Àwọn ìwé ìròhìn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pe Agbẹjọ́rò ní ìlú Kansas City fẹ́ di Ọba ní ilẹ̀ Yorùbá.
O ti le ni ogún ọdún ti ọmọ-ọba Adébáyọ̀ Ògúnmeno ti wà ní ilu Kansas City ní orilẹ-èdè Amẹ́ríkà, ṣùgbọ́n o wu Agbẹjọ́rò yi láti di Ọba ilu Ṣagamu ní Ìjẹ̀bú Rẹmọ.
Itọ́ka si ọ̀rọ̀ yi nínú ìwé ìròhìn
Nígbàtí mo jí ní àárọ̀ yi, otútù mu gidi gan ní. Mo lo si fèrèsé ilé mi láti wo ìta, mo si rí pe gbogbo ìta funfun láúláú. Gbogbo oníròhìn (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) lórí ẹ̀rọ (tẹlifíṣàn) móhùn-máwòrán ní wọn sọ̀rọ̀ nípa “Snow”. Èyí lo mu mi ṣe ìwádi nípa ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yi si èdè Yorùbá. Mọ wo ìwé ìtúmọ̀ èdè Yorùbá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n ìtúmọ̀ oríṣiríṣi ní àwọn ìwé yi fún mi.
Ìwé ìtúmọ̀ ti Ọ̀jọ̀gbọ́n Káyọ̀dé. J. Fákinlẹde ní pe “Snow” túmọ̀ si “yìnyín” tàbí “omi dídì”, ṣùgbọ́n ìwé ìtúmọ̀ ti ìjọ CMS tẹ jáde ní ọdún 1913 ní pe “Snow” tùmọ́ si “ìrì dídì”. Ìwé ìtúmọ̀ kẹ́ta ti mo wo ní pe “Snow” túmọ̀ si “òjò dídì”.
Kíni ẹ yin ro wi pe “Snow” ní èdè Gẹ̀ẹ́si, túmọ̀ si ní èdè Yorùbá?
Ìtọ́ka sí ìparí – Funfun láúláú »
láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)
Lẹ́hìn ÌFOJÚSÓDE, ohun tí ó kàn ni ALÁRINÀ. ALÁRINÀ jẹ́ ọ̀nà ìbára ẹni sọ̀rọ̀ láàrín ìdílé ọkọ àti aya tàbí láàrín ọkọ àti ìyàwó. Lẹ́hìn tí òbí báti rí obìnrin tàbí ọkùnrin fún ọmọ wọn; wọn yíò wá enìkan tí yíò jẹ alárinà láti ṣàlàyé èróǹgbà ọkàn wọn fún àwọn òbí ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn.

Alárinà le jẹ́ ọ̀rẹ́, aládùúgbò tàbí ọ̀kan nínú ẹbí àwọn òbí ọkùnrin tàbí tí obìnrin.
Lára àwọn ojúṣe Alárinà ni; ṣíṣe ìwaàdí lórí ẹbí tí ó fẹ́ lọ bá sọ̀rọ̀ nípa fífẹ́ ọmọ wọn.
Lẹ́hìn èyí ní yíò sọ fún bàbá ọmọ tí wọn fẹ́ fẹ́. Lọ́pọ̀lọpọ̀ igba ni wọ́n maa ní kí Alárinà maa
padà wá títí tí wọn yíò fí fun ní èsì. Tí àwọn òbí bá ti faramọ́ pé kí ọmọ wọ́n fẹ́ ọkùnrin
tí Alárinà torí rẹ̀ wá. Ohun tí ó kàn ní BÀBÁ GBỌ́, ÌYÁ GBỌ́.
- Ibéèrè àti Èsì nípa ọ̀rọ̀ oríṣiríṣi iṣòro ilé-ayé láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé

Ibéèrè
Olùdámọ́ràn Fọláṣadé,
Ilé-ayé yi ma sun mi o, ilé-ayé mi ni yi ooo.
Kíni ki nṣe?
Ran mi lọ́wọ́ ooo.
Ọkọ mi ní mo ti sanra jù,
o fún ni ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tínrín tàbí ki n kó jáde ní ilé ohun.
Kíni ki nṣe?
Àjọkẹ́
láti Ògbómọ̀ṣọ́
Èsì (láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé)
Àjọkẹ́ mi ọwọn,
Ọ̀rọ̀ nlá lo dé lẹ́ yi o, láti wà ní ilé ọkọ ní àṣà ilẹ̀ wa ṣe pàtàkì.
Ọ̀rọ̀ ti ọkọ rẹ̀ sọ ko burú rárá, ilera ni ọrọ̀ ooo, fún ànfàní rẹ̀ ṣi ní o.
Àjọkẹ́ o, ba ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ki o si pinu lati ṣe nkan nipa ọ̀rọ̀ yi.
Oríṣiríṣi nkan bi ìdárayá àbí ìjẹun níwọ̀nba l’o le ṣe,
bákànnáà gbìyànjú láti rí dokita rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yi.
Mo ro wipe èsì yi, yi o ran ẹ lọwọ́.
Àjọkẹ́ o, o ri ayọ̀, ọkàn rẹ̀ yi o ṣi balẹ̀ – Olùdámọ́ràn Fọláṣadé

Obì
Oriṣi obì meji l’ó wà:
Obì gidi, eyi ni àdáyébá,
a máa l’áwẹ́ mẹta si mẹfa,
ọdun keje si ẹkẹjọ ni sii saaba wọ ilé èso.
Awọn Ìjẹ̀ṣà si fẹran à ti máa gbin obì,
wọn si gbà pé, igi owó ($ £ ₦) ati igi ọrọ̀
ni ó jẹ́ fún awọn.
Eyi ni ó mú ki á máa ki Ìjẹ̀ṣà bayii:
Ìjẹ̀ṣà ó sun ore,
Ọmọ onilé obi,
Ìjẹ̀ṣà o sun ore,
Ọmọ olóbì wọ́ọ́wọ́ntiwọ́,
Ọmọ olóbì wọ̀ọ̀wọ̀ntiwọ̀,
Ọmọ Ìjẹ̀ṣà ti yoo bá ọrọ̀ kú,
Bí o bá fún unn l’óbì kan ṣoṣo
A máa so l’ábo l’ábo.
Eyi ti yoo bá òṣì ku,
Bi o báfún un l’óbì kan. A máa so l’akọ l’ákọ.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìjẹ̀ṣà àti Obì »
Èsì àwọn ènìyàn
09/08/2010 (9:14) Ìṣọ̀kan
09/08/2010 (6:18) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé