
Ọ̀kan nínú àwon olùdásílẹ̀ ibùdó ayélújára afinihàn (tàbí ìwé a fi ojú ẹni mọ̀ ní) èyí ti a npe ni “Facebook” ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ti o tún jẹ́ olùpilẹ̀ṣẹ̀ ibùdó ayélújára t’olóṣèlú MyBarackObama.com, Ọ̀gbéni Chris Hughes, ti dá ibùdó titun sílẹ lori ẹ̀rọ ayélújára.
Jùmọ̀ – ọkan nínú ọ̀rọ̀ èdè Yorùbá ni orúkọ ti wọn fi sọ ibùdó ayélújára titun yìí – Jumo.com.
Ilé-iṣẹ́ titun máa wa orísirísi ọ̀nà láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn káàkiri gbogbo àgbáyé.
Ìtọ́ka sí ìparí – Olùdásílẹ̀ Facebook ti dá ibùdó titun sílẹ lori ẹ̀rọ ayélújára pẹ̀lú orúkọ Yorùbá »
Àjàyí la nki bayi pe:-

Àjàyí, ògídíolú,
Òlóló, oníkànga àjípọn,
Òbomi òṣùùrù wẹdà.
Ẹkùn baba ọdẹ
Ẹkùn pakọ̀rọ̀ wolẹ̀.
Ẹni Àjàyí gbà gbà gbà,
Ti ò le gbà tan, Igúnnugún ní í gba oluwarẹ.
Àjàyí ti nwẹ lódò,
Ìtọ́ka sí ìparí – Àjàyí (Oríkì Orúkọ àmútọ̀runwa) »
Ni ilẹ Yorùbá ọpọlọpọ ọmọ ni njẹ orúkọ àmútọrunwá.
Ọpọlọpọ idi ni ó wa fun sisọ ọmọ ni irú orúkọ bayìí,
bi aṣa yi si ti fi idi múlẹ tó larin awọn Yoruba, kò si
ọmọ ti yio jẹ orúkọ àmútọrunwá ti ẹnikẹni kò ni mọ iru orukọ
ti a sọ irú ọmọ báyìí, nitoripe awọn ọmọ ti a gba pe,
o gba sábàbi ọ̀tọ̀ wa ile aiye l’a nsọ l’orúkọ bẹ.
Bi abiyamọ ba bi ọmọ meji pọ̀ lẹkanṣoṣo,
orúkọ àmútọ̀runwa ni nwọn yio maa jẹ,
bi ọmọ ba gbe ibi k’ ọ́rùn jade ninu iya rẹ̀,
ọ̀run ni a gba pe iru ọmọ bayìí ti mu orukọ wa si ile aiye.
Ìtọ́ka sí ìparí – Orúkọ Àmútọ̀runwá »

Dàda, aládé orí jinbíti
Onímọ̀galà
Ẹran gbígbẹ ò níjàǹjá.
Dàda kò lè já
Ó làbúrò tó gbójú,
Ta làbúrò Dàda?
Ọya òrííriì
Ẹkùn àṣèké.
Ìṣẹ owó kì í ṣẹ Dàda,
Dàda olówó-ẹyọ
Èsì àwọn ènìyàn
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé
06/08/2010 (10:41) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/06/2010 (10:49) Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì