|
|
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yìí.
Gẹ́gẹbi a ti sọ ni ọ̀sẹ̀ to kọjá, àṣà kikọ ìlà si ojú jẹ́ ikan lara àwọn ohùn ti àwọn ìyá wa máa fi bùkún ẹwa ojú wọn ní ayé àtijọ́. Ṣùgbọ́n ko wọpọ mọ nítorí ìdí mẹ́ta:
- Akọ́kọ́, nítorí ọlaju: àwọn obìnrin ayé òde òní ri kikọ ìlà si ojú bi ohun ìbílẹ̀.
- Ìdí kéjì ní ìtìjú, nítorí yẹ́yẹ́ àti àpárá, gẹ́gẹbi ibéèrè báyi “ṣe ẹ ba kìnìún jà ní?”
- Ìdí kẹ́ta, ní òfin ti ìjọba gbé jáde ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ní ọdún 2006 àti ní ìpínlẹ̀ Ọsùn ni ọdún 2009 nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé.
Èyí jẹ́ ohun ti o jẹ ki ogunlọ́jọ̀ ìdílé pa àṣà yi rẹ.
Ní ayé atijọ, àwọn àgbèègbè àti ìlú máa kọ oríṣiríṣi ìlà ti wọn fi da ara wọn mọ̀. Bi àwọn ti a mọ̀ si Ọ̀yọ̀ l’oni, ti ni oríṣiríṣi ìlà ti wọn fi da ara mọ, ni àwọn Ẹ̀gbá, Ìjẹbú, Ifẹ̀, Oǹdó, Ijẹ̀ṣá, Èkìtì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ náà ni oríṣi ìlà ti wọn fún ọmọ ti wọn bá bi. Ẹ tẹ̀ ibi ti atọ́ka si, ni ìsàlẹ̀ yìí, láti rí afihàn àwọn aworan díẹ̀, ninu awọn oríṣiríṣi ìlà ti wọn kọ ni ilẹ̀ Yorùbá.
Ìtọ́ka sí ìparí – Àṣà ìlà kíkọ si ojú »
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yii.
Ni ọ̀sẹ̀ yii a máa wo oríriṣiríṣi nkan ti àwa obìnrin máa nlo ní àtijọ́ àti ode ìwòyí láti fi ṣe ojú wa l’eṣọ́.
Ní àtijọ́, ìla kikọ jẹ́ ohun ti o gbajúmọ̀ gaan ni láàrín àwọn obìnrin, (nítorí ìdí èyí ní ọ̀sẹ̀ ti o mbọ mo máa sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi ìla kikọ) ṣùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ mi lòní mo máa sọ̀rọ̀ nípa ohun míràn ti àwọn ìyá wa máa nlo ní àtijọ́ bi tìróò, osun, laalì, mọju àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Ní ayé àtijọ́ àwọn obinrin wa máa kun tìróò yika ojú won láti fi gbé ẹwà ojú wọn jáde gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin ode ìwoyí ṣe lo nkan ti a npe ní “eye pencil” ní èdè Gẹ̀ẹ́si.
Ìtọ́ka sí ìparí – Oge Ojú »
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yi.
Mo sọ ní ọ̀sẹ̀ ti o kọjá pe a o máa wo oríṣiríṣi nkan ti obìnrin ìwòyí àti ti àtijọ́ máa nlo láti jẹ ki ojú wa gun régé ṣùgbọ́n ki a to wo àwọn ohun wọ̀nyi, mo fẹ sọ̀rọ̀ ní ṣoki nípa ÌWÀ. Bi ẹ ṣe mọ̀ wípe ìwà lẹwà, wọn ní obìnrin sọ ìwà nù, ko ri ilé ọkọ gbe.
Mo fẹ́ rọ̀ yin ẹ yin obìnrin ẹgbẹ́ mi àti gbogbo ènìyàn ti nkà Ọrọ̀ yi wípe ki a fi ìwà ti o dára ṣayé.
Ẹ ba mi kalọ pẹ̀lú ewì (ìsàlẹ̀ yi).
Ìtọ́ka sí ìparí – Fìwàṣayé »
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Irun dídì àti Kikó ní àṣà Yorùbá jẹ́ lara ohún ti máa bùkún ẹwà fùn Obìnrin wa.
Bi a ba kọ́kọ́ ri obìnrin, irun orí jẹ́ ohùn ti a o wo, bóyá o dára tàbí ko dára.
A máa wo oríṣiríṣi irun dídì and kikó ti àtijọ́ àti ti òde ìwòyí.
 
Báwo ní a nṣe dí irun tàbí kó irun?
Ẹní ti o ba dí irun tàbí kó irun ní a pé ní “Onídìrí”
Onídírì yi o dí irun tàbí kó irun bi o ba ṣe fẹ́
tàbí ki o fi àwọn àwòrán irun dídì ati kikó hàn ẹ, ki o mú iru eyi to wu ẹ.
Ni ṣoki, ti o ba fẹ dì irun tàbí kó irun rẹ̀ , onídírì yi o la irun náà , ko to bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kikó tabi dídì.
Eyi ni diẹ ninu irun ayé atijọ
 
Ìtọ́ka sí ìparí – Irun dídì àti kikó »
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kú dédé àsìkò yi o.
Ẹ kábọ̀ si “Ayé Obìnrin“.
Ní ọ̀sẹ̀ yii, a o wo ipò Obìnrin gẹ́gẹbi Ìyá.
Bí wọn ti máa ńsọ wí pe:
“Ìyá ní wúrà”, àti wí pe “òrìṣà bi Ìyá o si”,
bẹ́ẹ̀ni o, òrìṣà bi Ìyá o si, bi ìyá abiyamọ tọ̀ọ́tọ́.
Ìyá ní o bí gbogbo wa,
Ìyá ni olùtọ́jú wa,
ipò Ìyá ko ṣe fi ọwọ́ rọ sẹ̀hìn rárá.
Gẹ́gẹ́bí orin àtijọ́ kan ṣe lọ báyi wí pe:
Ìyá ní wúrà iyebíye
Ti a ko le f’owó ra
O l’oyún mi fún oṣù mẹsan
O pọ̀n mi f’ọdún mẹ́ta
Ìyá ní wúrà iyebíye
Ti a ko le f’owó ra
Ha Ìyá, ohun ẹlẹgẹ́ ní o!
Ìyá ṣe pàtàkì ní àṣà ilẹ wa, ẹ rántí ilé.
Ẹ jẹ́ ka rántí ìyá ti o ṣe ọlọkọ̀ wa s’ayé.
Ẹ jẹ́ ka bu ọ̀wọ̀ àti iyì fún Ìyá wa.
Ìyá mi, wa pẹ l’ayé, Ìyá mi o, wa jèrè ọmọ.
Ìyá mi, abiyamọ tọ̀ọ́tọ́.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìyá ní wúrà »
láti ọwọ́ Ajialàrà
Irú ìgbésí ayé wo ní Obìnrin wà?
Obìnrin ní ìyá wá, olùrànlọ́wọ́, alábarò, ọ̀rẹ́, àbúrò, ẹ̀gbọ́n àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Wo àyíká rẹ̀ ki o sọ fún mi ipò ti obìnrin wá nínú ayé rẹ̀?
  
Gẹ́gẹbi Obìnrin, a o maa wo ní ìpele ní ìpele gbogbo nkan ti Obìnrin fi jẹ́ Obìnrin.
Ní ọ̀sẹ̀ to ḿbọ̀, a o sọ̀rọ̀ nípa Obìnrin gẹ́gẹ́bi Ìyá wà.
Ẹ kábọ̀ o, si “Ayé Obìnrin“.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ayé Obìnrin (ọ̀rọ̀ àsọṣaájú) »
Yorùbá ka kí a pe èniyàn ni ọmọlúàbí sí ohun ìwúrí, ìdùnnú, iyì àti ohun tí o ń fi bibíire àti ẹkọ́ ilé hàn. Fún idí yìí, ohun pàtàkì ni fún ẹnikẹni ki ó le gbìyànjú láti hu ìwá tí wọn yóò fi máa pè é ní ọmọlúàbí.
Ìwà-ipá nínú ilé, pàtàkì láti ọwọ́ ẹnití ti o jẹ alábagbé, ọrẹ́ tàbí ọkọ rẹ̀, le ṣẹlè si ẹ̀nikẹ̀ni, láìbìkítà fún ìpò ti ènìyàn wà, tàbí ẹ̀gbẹ́, tàbí ọjọ́ orí, obìnrin tàbí ọkùnrin, ẹsìn, bọ́yá ènìyàn ni abùku ará tàbí áwọ̀ ènìyàn.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìwà-ipá nínú ilé »
 
Alákoso ilé-ìṣe sinimá Ogbeni Damian Francisco Perez Tellez ti gbé fiìmù sinimá titun jáde nipa àwọn arábìnrin onilù Bàtá ní orílẹ̀-èdè Kúbà (Cuba). “Obini Bata” ni orúkọ ẹgbẹ́ onilù náà.
Àwọn ẹgbẹ onilù Bàtá púpọ̀ lo wà ní Kúbà, sugbọn ẹgbẹ́ “Obini Bata” àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdèe Kuba ti wọn jẹ obìnrin nìkan lo wà nínú ẹgbẹ́ onilù wọn.
Erékúsù ni Kúbà ni àgbèègbè ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdèe Kúbà ti wọn jẹ́ ènìyàn alàwọ̀ dúdú, lo gbé ìse àti àṣà Yorùbá larugẹ, ni orílẹ̀-edeé wọn. Nítorí ìdí èyí ní, ẹsìn ìbílẹ̀ Yorùbá àti ìlù Bàtá jẹ́ nkan pàtàkì ní ilẹ̀ Kúbà.
Itọ́ka-
http://www.cubarte-english.cult.cu/paginas/actualidad/noticia.php?id=11082
Láti ní àṣeyọrí ẹ́tọ́ àwọn ọmọdé o ṣe pàtàkì ki a fún ìlera àti àláfíà àwọn ìyá ni ikọbiarasi to yẹ.
Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀nà ni àwọn obìnrin fi nkopa to nipọn nínú ìwaláláfiá àwọn ọmọdé,
nítorí ìdí eyi, ìgbélarugẹ ipò àwọn obìnrin, àti ọ̀nà látí pèsè dọ́gbandọ́gba nípa ẹ̀kó, igbẹ̀kó,
ẹyawó àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn jẹ́ nkan to níyelóri púpọ̀ si àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè wa.
Ìtọ́ka sí ìparí – Obìnrin ṣe Pàtàkì »
|
|
Èsì àwọn ènìyàn
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé
06/08/2010 (10:41) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/06/2010 (10:49) Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì