Ìlù lílù

Yoruba Drums from Republic of Benin (i.e. Dahomey)
Inu didun nii mú araáya-wá,
ẹni ti inu rẹ̀ bá si dùn, ti ara rẹ̀ yá,
yoo yọ̀, yoo si jó, bayii ni awọn baba wa ṣe bẹrẹ iṣẹ́ ìlù,
nigba ti ó yá, ó di wi pe ọpọlọpọ nńkan ṣiṣe ni à ń lo ìlú fún,
ìlú si di iṣẹ idile awọn ẹbi kan. Irú awọn ẹbi wọnyi ni ń jẹ orukọ
bii Àyándélé, Onílúdé, Onígbìndé ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀.

Eyi ni diẹ ninu awọn ohun ti à ń fi ìlù ṣe:
Láyé atijo, bi ìletò kò bá jìn si ara wọn,
awọn ara ìletò kìíní lè fi ìlù ṣòfófó fún ti ekeji pe ogun dé.

(i) Fún idárayá ni ibi ìnáwó,
ìbáà ṣe ìgbeyàwó, ìnáwó ọdun titun, ìkómọjáde,
òkú egbodo ati ijó ẹgbẹ́ ati oriṣiriṣi àríyá;
(ii) Lati ji ọba l’ori ìtẹ́;
(iii) Fún ìyẹ́sí àlejó àtàtà;
(iv) Bi ohun èlò ìranlọwọ nigba ogun..

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ilé-Ifẹ̀

Ilé-Ifẹ̀ jẹ́ ìlú t’ó ṣe pàtàkì púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Ìtàn sọ wípé Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti Ilé-Ifẹ̀.
Odùduwà l’ẹni tí ó ṣẹ Yorùbá sílẹ.
Ifẹ̀ jẹ́ ìlú t’ó tóbi.
Ọpọlọpọ̀ ère l’ó wà ní Ilé-Ifẹ̀.
Ọpá Ọrányàn jẹ ohun t’ó ṣe pàtàkì ní Ilé-Ifẹ̀.
Odùduwà t’ó ṣẹ Yorùbá sílẹ̀ jẹ enìà tí o ṣe pàtàkì.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ilé-Ifẹ̀ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ògbómọ̀ṣọ́

Ògbómọ̀ṣọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú ti ó tóbi ní ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn ìlú tí ó yí Ògbomọ̀ṣọ́ ká ni Ọ̀yọ́, Ilọ́rin àti Èjigbò.
Ògbómọ̀ṣọ́ tọ́ bí máílì mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sí Ọ̀yọ́.
Àwọn oníṣẹ́ Ọlọ́run pọ̀ púpọ̀ níbẹ̀.
Àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní ìjọ Baptísì.
Nwọ́n kọ́ sọsì tí ó tóbi, nwọ́n si ní ilé iwé ti o pọ̀ púpọ̀ ni Ògbómọ̀ṣọ́.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ògbómọ̀ṣọ́ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA

Olumọláti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)

Abẹ́òkúta ìlú Ẹ̀gbá, ìlú Ẹ̀gbá Aké, ìlú Ẹ̀gbá Òwu, ìlú Ẹ̀gbá Òkè-Ọnà, ìlú Ẹ̀gbá Àgùrà, ìlú Ẹ̀gbá Ìbarà, ìlú Líṣàbi-Agbòǹgbò-àkàlà, ìlú Lámodi, ìlú Ajíbóyèdé, ìlú Ṣodẹkẹ́-ọmọ Ẹfúwọ̀ ìlú Olúmọ, ìlú abẹ́ òkúta. Abẹ́òkúta ìlú Ẹ̀gbá.

 

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter