Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)


- Ibéèrè àti Èsì nípa iṣòro ilé-ayé láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé

Ibéèrè?

Olùdámọ́ràn Fọláṣadé,
Mo dúpẹ́ lọwọ́ yin fún ìmọ̀ràn ti ẹ fún mi ni ọ̀jọ́sí wípe ki má kánjú ṣe ìgbéyàwó.
Afẹ́fẹ́ máa ti fẹ́, a ti rí fùrọ̀ adìẹ, àṣírí ti tú.
Níbo ní ki ti bẹ̀rẹ̀? Ní ṣókí, mo sọ fún ọkọ àfésọ́nà mi yìí, ki o fún ní àsìkò díẹ̀ ki a to lọ ṣe ìgbéyàwó ikọ̀kọ̀, o bínú gidigidi o ṣi sọ pe ohun yoo fún mi ní ọ̀sẹ̀ kan péré. Ní ọjọ́ kéjì, mo rí ọ̀rọ̀ kan ti fi wọn fi jíṣé lórí ẹrọ ibanisọrọ (èyí ti a npe ní “text message ” ní èdè Gẹ̀ẹ́si) ti arábìnrin kan kọ si ọkọ àfésọ́nà mi yìí (ńi ìgbà ti o lọ si balùwẹ̀) pe ki o wa rí ohun, ki o si mú owó oúnjẹ ọmọ lọwọ́? Orí mi l’ago, ki ní eléyìí, kíni ki nṣe? Tan ní ki fi ọ̀rọ̀ mi lọ? Èyí ní àwọn ibéèrè ti o wà lọ̀tún, lòsì, si ọkàn mi. Omije gba ojú mi, ha, ha ayé mi re ooo. Ṣe èpè ní ìfẹ́ ní, tàbí àgbéèlébú?
Kíni ki nṣe?
 

Émi ní,
Bọ́látítọ́

láti ìlú Èkó (Nàìjíríà)

 

Èsì (láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé)

Bọ́látítọ́,
Nu ojú rẹ̀, mú ra rẹ̀ giri, ko si ṣiṣe, ko si aiiṣe, a o ri irú eleyi ri, a fi dẹ́rùba ọlọ̀rọ̀ ní o.
Ti o ba ti dé ilẹ̀, o ti dé ilẹ̀ ní yẹn oo, nkan ti a máa ṣe ní o ní lati máa ro báyìí. Mo mọ̀ pe o ní ifẹ arákùnrin yìí. Gégébí ibéèrè rẹ̀ nípa ìfẹ́, ìfẹ́ ki nṣe èpè tàbí àgbéèlébú, adùn ní ìfẹ́ ṣùgbọ́n ní ìgbà míràn o máa mú kikorò lọwọ́ ṣùgbọ́n, òtítọ́ dára nínú ifẹ. Èmi yio gbá o ní ìyanjú láti wádìí nípa ọmọbìnrin náà àti ọmọ rẹ̀ dáradára ki o to kọ ọkọ àfésọ́nà rẹ̀ yìí lojú. Ṣe ìwádìí lọwọ́ àwọn ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, ará àdúgbò àti ẹbí ọkọ àfésọ́nà rẹ̀.
Bákànnáà, ti o ba mọ̀ bi o ṣe lè pe arábìnrin náà lórí ẹrọ ibanisọrọ, o lè pe láti ṣe ètò bi ẹ ṣe lè pade.
Bi mo ṣe sọ siwaju, ko si ohun ti nbọ̀ lòkè ti ilẹ̀ o le gbá.
Jẹki mọ àbábọ̀ iwadi rẹ

L’ayọ̀ o!
- Olùdámọ́ràn Fọláṣadé

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ìtàn Sẹ̀gilọlá ní èdè Yorùbá lóri ẹ̀rọ ibanisọ̀rọ̀ alagbéka

Segilọla free iPhone App

Ẹ tẹ ibi ti atọ́ka si ní ibi, láti lọ si “iTunes” fún gbígba ànfàní èlò-ìṣẹ́ (ti a gbé jáde ní nípa) ìtàn Sẹ̀gilọlá (ní èdè Yorùbá) si ori ẹrọ ibanisọ̀rọ̀ yin, lọ́fẹ.

http://itunes.apple.com/us/app/id315429167?mt=8

Ìtọ́ka sí ìparí – Ìtàn Sẹ̀gilọlá ní èdè Yorùbá lóri ẹ̀rọ ibanisọ̀rọ̀ alagbéka »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Èlò-ìṣẹ́ ẹ̀rọ ibanisọ̀rọ̀ alagbéka fún oríṣiríṣi orúkọ (16,452) ọmọ Yorùbá


Ẹ tẹ ibi ti atọ́ka si ní ibi, láti lọ si “iTunes”
fún gbígba ànfàní èlò-ìṣẹ́ Orúkọ Yorùbá yi,
si ori ẹrọ ibanisọ̀rọ̀ yin lọ́fẹ

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter