Ìjẹ̀ṣà àti Obì

Obi

Obì

Oriṣi obì meji l’ó wà:
Obì gidi, eyi ni àdáyébá,
a máa l’áwẹ́ mẹta si mẹfa,
ọdun keje si ẹkẹjọ ni sii saaba wọ ilé èso.

Awọn Ìjẹ̀ṣà si fẹran à ti máa gbin obì,
wọn si gbà pé, igi owó ($ £ ₦) ati igi ọrọ̀
ni ó jẹ́ fún awọn.

Eyi ni ó mú ki á máa ki Ìjẹ̀ṣà bayii:
Ìjẹ̀ṣà ó sun ore,
Ọmọ onilé obi,
Ìjẹ̀ṣà o sun ore,
Ọmọ olóbì wọ́ọ́wọ́ntiwọ́,
Ọmọ olóbì wọ̀ọ̀wọ̀ntiwọ̀,
Ọmọ Ìjẹ̀ṣà ti yoo bá ọrọ̀ kú,
Bí o bá fún unn l’óbì kan ṣoṣo
A máa so l’ábo l’ábo.
Eyi ti yoo bá òṣì ku,
Bi o báfún un l’óbì kan. A máa so l’akọ l’ákọ.

Oriṣi obì keji ni obì gbàǹja tabi góórò.
Ọdun karunun ni obi yii wọ ile èso.
Bi eniyan bá ń jẹ ẹ́, omi rẹ̀ a máa pọ́n,
eyín ẹni ti ó si ń jẹẹ a máa pọ́n,
awọn eniyan a si máa sọ pé
“eyín rẹ̀ pọ́n bíì eyín in ajẹgóórò”.
Awẹ́ meji ni obì yii ni, awọn ara òkè Ọya sì fẹran rẹ̀ni jijẹ.
Gbàǹja kan wà ti ó funfun ti kì í sìí ni pupa rara,
eyi ni awọn àgbẹ̀ ń pé ni gbàǹja olókukù lati fi agbègbè
ibi ti ó ti pọ̀ ati ibi ti ó gbọ igi obì yii hàn. – láti inú ìwé C. L. Adéoyè.

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter


Ẹ fi àwọn ìka òòtẹ̀-ìwé wa, kọ̀ èrò ọkàn yín, nípa ọ̀rọ̀ yìí

 

 

 

Ẹ lè lo awọn àmì Ayélújára

<a href="" title=""> <abbr title=""> <acronym title=""> <b> <blockquote cite=""> <cite> <code> <del datetime=""> <em> <i> <q cite=""> <strike> <strong>

Fèsì lórí Facebook (ibùdó ayélújára afinihàn tàbí ìwé a fi ojú ẹni mọ̀ ní)