Ìkíni jẹ́ àṣà pàtàkì ninú àwọn àṣà Yorùbá.
Èyí ni díẹ̀ ninú ìkíni fún àkànṣe àti oríṣiriṣi àsikò ní ilẹ̀ Yorùbá:-
1.) Ẹni tí ó bímọ:-
(a) Mo yọ̀ fún ọ
(b) Ayọ̀ abara tintin
(d) Ẹ kú ewu ọmọ
(e) Bárikà tí a gbọ́ ohùn iyá àti ọmọ
Ìdáhùn - Ayọ̀ yóò kárí o!
2). Ẹni tí ó ń gbéyàwó
(a) Ẹhin ìyàwó kò ní mọ ẹni
Ìdáhùn -Àwa nùun
(b) Wòyi oṣu mẹsàn-án ìlasa ọmọ ni a ó máa jẹ
Ìdáhùn – Aṣẹ o!
(d) Ẹ kú ọwọ l’ómi
(e) Ẹ kú láàsigbò
(ẹ) Òwò èrè ni Olúwa yóò é o
3). Fún ìdágbére:-
Ìpàdé wa bii oyin
Ọlọ́run má kọ àtúnrí
Ọlọ́run kò ní i ṣe èyi i’árìmọ
Ìdáhùn:
Àṣẹ, Ọlọrun yọ́ọ̀ dá ẹ̀mí wa sí
4). Ní ìgbà òtútú – Ẹ kú òtútú yìí
Ìdáhùn – Kò sí bí ò ti ri !
5). Ní àsìkò ọdún :-
(a) Ẹ kú ọdún
(b) Ẹ kú ìyèdún
(d) Ọdún ó ya abo
(e) Ẹ̀mí yóò rí òpin ọdún
Ìdáhùn - Àmín
6). Ní ìgbàkúùgbà:-
Ẹ kú ìgbà t’ó dé
Ẹ kú àsikò yí
Ìdáhùn:
Kí Ọlọrun fún wa ní àsìkò rere.
Kí Ọlọrun mú ìgbà dáradára wá
7). Àsìkò ọ̀gbẹlẹ̀ tàbí ẹ̀ẹrùn:-
(a) Ẹ kú ọ̀gbẹlẹ
(b) Ẹ kú ọ̀gbẹle
(d) Ẹ kú ọ̀dá yìí
Ìdáhùn – Kò ṣẹ-kò ṣẹ
8). Ní ìgba ọ̀gìnnìtìn - Ẹ kú ọ̀ginnìtìn
Ìdáhùn – Àwa nùun
9). L’áàrin òru - Oru kò mọ ọlọ̀wọ̀ (Li ó dífá fún ìwọ ta ni)
Ìdáhùn – Emi [......] ni o
10). Ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dìde àìsàn:-
(a) Ẹ kú ewu
(b) Báríkà ẹsẹ̀ tí ó tẹlẹ̀
Ìdáhùn – Ọpẹ ni fún Olúwa
tabí
Ìdáhùn – Mo dúpẹ́
11). Ẹni tí ó sin ọmọ:-
(a) Nisisyi ni yóò wálé o!
Idahun – Àṣẹ, tiyín náà yòó dára o
(b) Olúwa yóò fi ààyè gbà á
(d) Ọlọrun yóò pè é l’ áya re
(e) Kò ni í bá orogún búburú pàdé



