|
|
Ibéèré méjì láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọ̀ṣíndẹ̀kọ́ ní ìlú Ìbàdàn)
1. Kíni àwọn nọ́mbà wọ̀nyí ní òǹkà Yorùbá – 20, 38, 50 ?
2. Ṣé lóòtọ́ ni pé Odùduwà ní baba ńlá Yorùbá?
Ṣàlàyé ìdáhùn rẹ.
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yi.
Mo sọ ní ọ̀sẹ̀ ti o kọjá pe a o máa wo oríṣiríṣi nkan ti obìnrin ìwòyí àti ti àtijọ́ máa nlo láti jẹ ki ojú wa gun régé ṣùgbọ́n ki a to wo àwọn ohun wọ̀nyi, mo fẹ sọ̀rọ̀ ní ṣoki nípa ÌWÀ. Bi ẹ ṣe mọ̀ wípe ìwà lẹwà, wọn ní obìnrin sọ ìwà nù, ko ri ilé ọkọ gbe.
Mo fẹ́ rọ̀ yin ẹ yin obìnrin ẹgbẹ́ mi àti gbogbo ènìyàn ti nkà Ọrọ̀ yi wípe ki a fi ìwà ti o dára ṣayé.
Ẹ ba mi kalọ pẹ̀lú ewì (ìsàlẹ̀ yi).
Ìtọ́ka sí ìparí – Fìwàṣayé »
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ọ̀gbẹ́ni dirẹba (awakọ̀) àti pasitọ (àlùfáà) ṣaláìsí si àsìkò kan náà. Ní ìgbà ti wọn dé ibodè ọ̀run. Oníbodè kí wọn kábọ̀. O si fún direba ni adé wúrà àti aṣọ ọba pẹ̀lú ọ̀pá idẹ. Bẹ́ẹ̀ si ní o fún pasito ní aṣọ lásán àti ọ̀pá igi. Èyí jẹ́ iyalenu nlá fún pasitọ. O wa béèrè lọ́wọ́ oníbodè wípe: “oníbodè o, ẹ́ẹ̀ṣe ti ẹ fún dirẹba lásánlásán ni ohun wúrà?” àti pe oun ti jẹ́ pasitọ fún ọgbọ̀n ọdún. Oníbodè rẹ̀rín ha ha ha ha! O si wípe “pasitọ aṣeyori (àti èsì) la máa nwo ní ibí yi, ti dirẹba yi ba wa ọkọ̀ àwọn ènìyàn máa ngba àdúrà gidi gaan ní ṣùgbọ́n ti ìwọ pasitọ ba ṣe ìwàásùn àwọn ènìyàn máa sùn………
Ẹ̀rín kékéké ooo, ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi nro mi ooooo :-D :-D
láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)
Bàbá gbọ́, Ìyá gbọ́ ni ó kàn lẹ́hìn tí Alárinà báti tọrọ ọmọbìrin náà fún fífẹ́. Èyí jẹ́ ọ̀nà tí àwọn òbí ọmọbìrin náà fi fara mọ́ ìgbeyàwó láàrín ọmọ wọn àti ọmọkùnrin tí Alárinà wá sọ nípa rẹ̀. Tí ọmọbìrin náà sì ti jẹ́ oo; èyí túmọ̀ sí ÌSÍHÙN. Ìdílé ọmọkùnrin yí ó fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn òbí ọmọbìnrin náà. Lẹ́hìn, èyí ni ìdána.
Nígbàtí mo jí ní àárọ̀ yi, otútù mu gidi gan ní. Mo lo si fèrèsé ilé mi láti wo ìta, mo si rí pe gbogbo ìta funfun láúláú. Gbogbo oníròhìn (ní èdè Gẹ̀ẹ́sì) lórí ẹ̀rọ (tẹlifíṣàn) móhùn-máwòrán ní wọn sọ̀rọ̀ nípa “Snow”. Èyí lo mu mi ṣe ìwádi nípa ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ yi si èdè Yorùbá. Mọ wo ìwé ìtúmọ̀ èdè Yorùbá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n ìtúmọ̀ oríṣiríṣi ní àwọn ìwé yi fún mi.
Ìwé ìtúmọ̀ ti Ọ̀jọ̀gbọ́n Káyọ̀dé. J. Fákinlẹde ní pe “Snow” túmọ̀ si “yìnyín” tàbí “omi dídì”, ṣùgbọ́n ìwé ìtúmọ̀ ti ìjọ CMS tẹ jáde ní ọdún 1913 ní pe “Snow” tùmọ́ si “ìrì dídì”. Ìwé ìtúmọ̀ kẹ́ta ti mo wo ní pe “Snow” túmọ̀ si “òjò dídì”.
Kíni ẹ yin ro wi pe “Snow” ní èdè Gẹ̀ẹ́si, túmọ̀ si ní èdè Yorùbá?
Ìtọ́ka sí ìparí – Funfun láúláú »
 
Oṣù kéjì ọdún ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà (USA) jẹ́ àsìkò ti wọn máa ṣe ìrántí ìtàn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ti o jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nínú oṣù yi, ní àwọn ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà máa bojúwo ẹ̀hìn láti rántí onírúurú ohun ti o ṣẹlẹ̀ si ènìyàn aláwọ̀-dúdú ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni sáà kan. Iṣe ribiribi ti Martin Lurther King àti àwọn aṣíwájú òmìrán, ṣe láti jà fún ẹ̀tọ́ àti ìgbélarugẹ ipò àwọn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ni ilẹ̀ Amẹ́ríkà pẹ̀lú ọ̀nà látí pèsè dọ́gbandọ́gba nípa:
- ẹ̀tọ́ lati dìbò,
- ẹ̀kọ́ fún ọmọ ilé-ìwé làìsí òfin láti ya ọmọ aláwọ̀-dúdú sọ́tọ̀,
- ẹyawó láti ra ile,
- àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn,
jẹ́ nkan ìwuri nlá fún gbogbo ènìyàn aláwọ̀-dúdú ka kiri àgbáyé.
Nítọrí àṣeyọrí ìjà fún ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ní ilẹ̀ Amerika, ní àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá fi pọ̀ ka kiri àwọn ìpínlẹ̀ àti ìlú Amerika. Ko si ìlú pàtàkì ní Amerika, ti ẹ ti ní ri ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá, bo jẹ ìlú Atlanta (ní ìpínlẹ̀ Georgia) tàbí ìlú Houston (ní ìpínlẹ̀ Texas) tàbí ìlú nlá New York.
Gẹ́gẹbi ẹ ti mọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn baba-nlá àwọn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ti o jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní wọn kó lẹrú láti ilẹ̀ Yorùbá ní ayé àtijọ́. Ọ̀kan nínú wọn ní Thomas Peters to jẹ́ ọmọ bíbí Ẹgba, ti wọn bí ní ọdún 1738. Wọn kó Thomas Peters l’eru láti ilẹ̀ Yorùbá ni ọdún 1760. Thomas Peters jẹ́ ọ̀kan lará àwọn jagunjagun ti o jà nínú Ogun Òmìnira fún orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọdún 1775 – 1783. Ní ìsàlẹ̀ ọ̀rọ̀ ti ẹ nkà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyi, mọ tọ́ka si àwòrán móhùn-máwòrán kan ti ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kan ṣe, ní èdè Yorùbá. Nínú móhùn-máwòrán yi, ẹ máa rí bi arákùnrin náà nṣe gbìyànjú láti kọ́ èdè Yorùbá. Gẹ́gẹbi ọ̀rọ̀ ti ọmọ Amẹ́ríkà náà sọ, nínú móhùn-máwòrán “èdè Yorùba dún láti kọ́”. Ire o! Ìtọ́ka sí ìparí – Oṣù fún ìtàn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ní Amẹ́ríkà (USA): Ọmọ bíbí Ẹgba Thomas Peters jagun ní Ogun Òmìnira Amẹ́ríkà (1775 – 1783) »
láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)
Lẹ́hìn ÌFOJÚSÓDE, ohun tí ó kàn ni ALÁRINÀ. ALÁRINÀ jẹ́ ọ̀nà ìbára ẹni sọ̀rọ̀ láàrín ìdílé ọkọ àti aya tàbí láàrín ọkọ àti ìyàwó. Lẹ́hìn tí òbí báti rí obìnrin tàbí ọkùnrin fún ọmọ wọn; wọn yíò wá enìkan tí yíò jẹ alárinà láti ṣàlàyé èróǹgbà ọkàn wọn fún àwọn òbí ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́ fún ọmọ wọn.

Alárinà le jẹ́ ọ̀rẹ́, aládùúgbò tàbí ọ̀kan nínú ẹbí àwọn òbí ọkùnrin tàbí tí obìnrin.
Lára àwọn ojúṣe Alárinà ni; ṣíṣe ìwaàdí lórí ẹbí tí ó fẹ́ lọ bá sọ̀rọ̀ nípa fífẹ́ ọmọ wọn.
Lẹ́hìn èyí ní yíò sọ fún bàbá ọmọ tí wọn fẹ́ fẹ́. Lọ́pọ̀lọpọ̀ igba ni wọ́n maa ní kí Alárinà maa
padà wá títí tí wọn yíò fí fun ní èsì. Tí àwọn òbí bá ti faramọ́ pé kí ọmọ wọ́n fẹ́ ọkùnrin
tí Alárinà torí rẹ̀ wá. Ohun tí ó kàn ní BÀBÁ GBỌ́, ÌYÁ GBỌ́.
láti ọwọ́ Ajialàrà.
Irun dídì àti Kikó ní àṣà Yorùbá jẹ́ lara ohún ti máa bùkún ẹwà fùn Obìnrin wa.
Bi a ba kọ́kọ́ ri obìnrin, irun orí jẹ́ ohùn ti a o wo, bóyá o dára tàbí ko dára.
A máa wo oríṣiríṣi irun dídì and kikó ti àtijọ́ àti ti òde ìwòyí.
 
Báwo ní a nṣe dí irun tàbí kó irun?
Ẹní ti o ba dí irun tàbí kó irun ní a pé ní “Onídìrí”
Onídírì yi o dí irun tàbí kó irun bi o ba ṣe fẹ́
tàbí ki o fi àwọn àwòrán irun dídì ati kikó hàn ẹ, ki o mú iru eyi to wu ẹ.
Ni ṣoki, ti o ba fẹ dì irun tàbí kó irun rẹ̀ , onídírì yi o la irun náà , ko to bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kikó tabi dídì.
Eyi ni diẹ ninu irun ayé atijọ
 
Ìtọ́ka sí ìparí – Irun dídì àti kikó »
- Ibéèrè àti Èsì nípa ọ̀rọ̀ oríṣiríṣi iṣòro ilé-ayé láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé

Ibéèrè
Olùdámọ́ràn Fọláṣadé,
Ilé-ayé yi ma sun mi o, ilé-ayé mi ni yi ooo.
Kíni ki nṣe?
Ran mi lọ́wọ́ ooo.
Ọkọ mi ní mo ti sanra jù,
o fún ni ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tínrín tàbí ki n kó jáde ní ilé ohun.
Kíni ki nṣe?
Àjọkẹ́
láti Ògbómọ̀ṣọ́
Èsì (láti ọwọ́ Olùdámọ́ràn Fọláṣadé)
Àjọkẹ́ mi ọwọn,
Ọ̀rọ̀ nlá lo dé lẹ́ yi o, láti wà ní ilé ọkọ ní àṣà ilẹ̀ wa ṣe pàtàkì.
Ọ̀rọ̀ ti ọkọ rẹ̀ sọ ko burú rárá, ilera ni ọrọ̀ ooo, fún ànfàní rẹ̀ ṣi ní o.
Àjọkẹ́ o, ba ọkọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ki o si pinu lati ṣe nkan nipa ọ̀rọ̀ yi.
Oríṣiríṣi nkan bi ìdárayá àbí ìjẹun níwọ̀nba l’o le ṣe,
bákànnáà gbìyànjú láti rí dokita rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yi.
Mo ro wipe èsì yi, yi o ran ẹ lọwọ́.
Àjọkẹ́ o, o ri ayọ̀, ọkàn rẹ̀ yi o ṣi balẹ̀ – Olùdámọ́ràn Fọláṣadé
Ìwé titun ti Ọ̀jọ́gbọ́n Ngugi wa Thiongo gbé jáde ní ọdún 2009 ní èdè Gẹ̀ẹ́sì èyí ti àkọlé rẹ̀ túmọ̀ si “Nkan titun fún Àtúnbí ilẹ Afirika” ṣe àlàyé to jinlẹ̀ nípa èrò ọkàn Ọ̀jọ́gbọ́n Ngugi lóri ìlò èdè àbínibí. Láti ìgbàtí Ọ̀jọ́gbọ́n Ngugi ti gbé ìwé ti wọn ni kọ ni ọdún 1982 jáde (èyí ti àkọlé rẹ̀ túmọ̀ si “Òmìnira Ọkàn”) ní Ọ̀jọ́gbọ́n náà ti ń sọ̀rọ̀ nípa bi o ti ṣe jẹ́ nkan pàtàkí ki àwọn ènìyàn ilẹ̀ Áfíríkà máa lò èdè àbínibí fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú àwọn orílẹ̀-èdè wọn. Nítorí idi pàtàkì yí, ní èdè Yorùbá fi jẹ́ nkan pàtàkì lóri Yorùbá Gbòde ní ayélújára Abeokuta.ORG
|
|
Èsì àwọn ènìyàn
09/08/2010 (9:14) Ìṣọ̀kan
09/08/2010 (6:18) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé