
Ìkíni jẹ́ àṣà pàtàkì ninú àwọn àṣà Yorùbá.
Èyí ni díẹ̀ ninú ìkíni fún àkànṣe àti oríṣiriṣi àsikò ní ilẹ̀ Yorùbá:-
1.) Ẹni tí ó bímọ:-
(a) Mo yọ̀ fún ọ
(b) Ayọ̀ abara tintin
(d) Ẹ kú ewu ọmọ
(e) Bárikà tí a gbọ́ ohùn iyá àti ọmọ
Ìdáhùn - Ayọ̀ yóò kárí o!
2). Ẹni tí ó ń gbéyàwó
(a) Ẹhin ìyàwó kò ní mọ ẹni
Ìdáhùn -Àwa nùun
(b) Wòyi oṣu mẹsàn-án ìlasa ọmọ ni a ó máa jẹ
Ìdáhùn – Aṣẹ o!
(d) Ẹ kú ọwọ l’ómi
(e) Ẹ kú láàsigbò
(ẹ) Òwò èrè ni Olúwa yóò é o
3). Fún ìdágbére:-
Ìpàdé wa bii oyin
Ọlọ́run má kọ àtúnrí
Ọlọ́run kò ní i ṣe èyi i’árìmọ
Ìdáhùn:
Àṣẹ, Ọlọrun yọ́ọ̀ dá ẹ̀mí wa sí
4). Ní ìgbà òtútú – Ẹ kú òtútú yìí
Ìdáhùn – Kò sí bí ò ti ri !
5). Ní àsìkò ọdún :-
(a) Ẹ kú ọdún
(b) Ẹ kú ìyèdún
(d) Ọdún ó ya abo
(e) Ẹ̀mí yóò rí òpin ọdún
Ìdáhùn - Àmín
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìkíni (Yorùbá) fún àkànṣe àti oríṣiriṣi àsikò »
Ìtọ́ka sí ayélújára ní èdè Faransé (Français) ńibí ti wọn ti tò lẹ́sẹẹsẹ oríṣiríṣi ìkíni Yorùbá to le ní igba (200), ti wọn lo ní orílẹ̀-èdè Bẹ̀nẹ̀n (Benin) nílẹ̀ Idàhọ̀mi :-
http://www.beninensis.net/Salutations_Yoruba.htm

láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)
Bójúmọ́ báti mọ́, ẹ̀ jí ire bí ni à ńkí ara ẹni.
Bọ́mọdé bá rágbà wọn à kìwọn pé kẹ́ẹpẹ́ baba.
Onídírì làńkí pé – Ojú gbooro.
Wọ́n á dáhùn pé – Òyà yíó yà.
Alágbẹ̀dẹ – Àrọyè o.
Ìdáhùn – Ògún á gbè ọ́.
Àgbẹ̀ - Àroko bá ọdún dé. Aláró – Àrẹdú.
Ìdáhùn – Ìyá Màpó á gbè ọ́.
Akọ̀pẹ - Ìgbà á rọ́ o. Ọdẹ – Àrìǹpa tògún.
Ìdáhùn – Ògún á gbè ọ́.
Afíńgbá - Ẹ kú ẹ̀rọ̀ ògún.
Ìdáhùn – Onírèse á gbè ọ́. Ìtọ́ka sí ìparí – ÌKÍNI NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ »

Ilé-ọjà “Yorùbá Book Center” ní ìlú New York (ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà) jẹ ́ọ̀kan nínú àwọn ilé-ọjà ti wọn ti n ta ìwé pẹ̀lú oríṣiríṣi nkan nípa àṣà àti ise Yorùbá to sopọ mọ ẹ̀sìn ìbílẹ̀ Yorùbá ní òkè-òkun ti a ńpe ní Santeria.
Eyi ni àdírẹsì ilé-ọjà yi:
610 (ní òpópó) New York Avenue,
Brooklyn,
New York 11203
Ìtọ́ka sí ìparí – Ilé-ọjà ìwé Yorùbá ní ìlú New York »
Èsì àwọn ènìyàn
09/08/2010 (9:14) Ìṣọ̀kan
09/08/2010 (6:18) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé