Èyí tí a bá wí fọ́gbọ́
Lọgbọ́ ń gbọ́.
Èyí tí a bá wí fọ́gbà
Lọgbà ń gbà.
Kọ́ṣẹkọ́ṣẹ n tìlákọṣẹ
Igbó rere talákẹdun
Omi kì í sàn
Kó bojú wẹ̀hìn
Àbótán lejò báwọọ rẹ̀.
Igbó réré
Igbó réré nilé alákẹdun
Omi kì í sàn
Kó bojú wẹ̀hin.
Àlọ rámirámi là á rí
A kì í rábọ̀ọ rẹ̀.
Igbó réré
Igbó réré
Igbó réré nilé alákẹdun.
Omi kì í sàn
Ìtọ́ka sí ìparí – Ọfọ̀ »
Èyí ni Òwe òní :-
Ẹyẹ ò sọ fún ẹyẹ pé òkò ḿbọ̀.
Ta lo mọ ìtúmọ̀ òwe yi?
Láti ní àṣeyọrí ẹ́tọ́ àwọn ọmọdé o ṣe pàtàkì ki a fún ìlera àti àláfíà àwọn ìyá ni ikọbiarasi to yẹ.
Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọ̀nà ni àwọn obìnrin fi nkopa to nipọn nínú ìwaláláfiá àwọn ọmọdé,
nítorí ìdí eyi, ìgbélarugẹ ipò àwọn obìnrin, àti ọ̀nà látí pèsè dọ́gbandọ́gba nípa ẹ̀kó, igbẹ̀kó,
ẹyawó àti àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ míràn jẹ́ nkan to níyelóri púpọ̀ si àwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀-èdè wa.
Ìtọ́ka sí ìparí – Obìnrin ṣe Pàtàkì »
Ẹ lu Agogo, ẹ lu Agogo,
Ẹ lu Agogo Kérésìmesì, ẹ lu Agogo.
Ẹ lu Agogo, Olùgbàlà de o.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ẹ lu Agogo Kérésìmesì »
Kérésìmesì, ọdún dé, ọdún olówó.
Kérésìmesì, ọdún dé.
Kérésìmesì, ọdún dé, ọdún ọlọmọ.
Kérésìmesì, ọdún dé.
Kérésìmesì, ọdún dé, ọdún ìgbàgbọ́.
Kérésìmesì, ọdún dé.
A ṣéṣé tún ṣé.
Ìtọ́ka sí ìparí – Kérésìmesì – ọdún dé »
Ìtọ́ka sí Ìwé-ẹ̀rí fun ètò ẹ̀kọ́ Yorùbá ni orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì (UK):
1. Ìwé-ẹ̀rí kíní
2. Ìwé-ẹ̀rí kéjì
Ni ilẹ Yorùbá ọpọlọpọ ọmọ ni njẹ orúkọ àmútọrunwá.
Ọpọlọpọ idi ni ó wa fun sisọ ọmọ ni irú orúkọ bayìí,
bi aṣa yi si ti fi idi múlẹ tó larin awọn Yoruba, kò si
ọmọ ti yio jẹ orúkọ àmútọrunwá ti ẹnikẹni kò ni mọ iru orukọ
ti a sọ irú ọmọ báyìí, nitoripe awọn ọmọ ti a gba pe,
o gba sábàbi ọ̀tọ̀ wa ile aiye l’a nsọ l’orúkọ bẹ.
Bi abiyamọ ba bi ọmọ meji pọ̀ lẹkanṣoṣo,
orúkọ àmútọ̀runwa ni nwọn yio maa jẹ,
bi ọmọ ba gbe ibi k’ ọ́rùn jade ninu iya rẹ̀,
ọ̀run ni a gba pe iru ọmọ bayìí ti mu orukọ wa si ile aiye.
Ìtọ́ka sí ìparí – Orúkọ Àmútọ̀runwá »
Èsì àwọn ènìyàn
09/08/2010 (9:14) Ìṣọ̀kan
09/08/2010 (6:18) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé