Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì

láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yìí, a o máa wo ikan lara oúnjẹ ilẹ̀ wa tí a pè ní ẹ̀wà.
Bi orin àtijọ́ kan ṣe lọ bàyìí wípè:
Epo nbẹ, ẹ̀wà nbẹ oo
Epo nbẹ, ẹ̀wà nbẹ oo
Àyà mi o ja láti bí béjì
Epo nbẹ, ẹ̀wà nbẹ oo
Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì.

Ẹ̀wà jẹ́ oúnjẹ ti o gbajúmọ̀ nínú gbogbo ayé, bákànnáà ní a ní oríṣiríṣi ẹ̀wà. Ní ilẹ̀ Yorùbá, a máa fi ẹ̀wà se àwọn oúnjẹ bi àkàrà, mọ́-ín mọ́-ín tàbí ọ̀lẹ̀ lẹ̀, a ṣi tún máa se ẹ̀wà àgbàdo, iṣu, àti ọ̀gẹ̀dẹ̀.
Ẹ̀wà aládùn kan ti wọn pè ní ẹ̀wà àgànyin wọ́pọ̀ ní ìlú Èkó. Irú oúnjẹ wo ní o lè fi se ẹ̀wà, ti a o ti darúkọ níbi?

Ìtọ́ka sí ìparí – Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Iṣu paradà o di iyán


Tradução para portuguêsláti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yìí, a máa wo oríṣiríṣi ọ̀nà ti a fi lè jẹ iṣu.
A lè se iṣu, a lè dín iṣu, a lè sun iṣu.
Iṣu jẹ ikan nínú àwọn oúnjẹ ti o wọpọ ní ilẹ̀ Yorùbá. Njẹ́ ẹ mọ̀ pe iyán jẹ́ oúnjẹ ti o gbajúmọ̀ jù lọ lára oúnjẹ ilẹ̀ wa? Ti a ba ní ṣiṣe, ti iyán o ba si lára oúnjẹ ti a o fi ṣe àlejò, àsè náà o ti pé.

niger-2007_1196263620_nigeria_2007_008

 Báwo la ṣe máa sọ iṣu di iyán?
Ti a ba fẹ́ sọ iṣu di iyán, a o gbé àwọn ìgbesẹ́ ìsàlẹ yìí. Ìkoko, ọbẹ̀, iṣu, omi, odó, ọmọ odó àti abọ́ ní àwọn nkan ti a máa lo.
1). A o bẹ iṣu, a o ṣi gé si kékèké, a o ṣan isu si inú ìkókó pẹ̀lú omi díẹ̀, ti a máa fi se iṣu náà.
2). A wa gbé ìkòkò iṣu yìí si orí ohun ìdáná ti a fẹ́ lo, ti iṣu náà ba wa lórí iná fún ìṣéjú mẹ́wàá, a o wo bóyá o ti jiná to láti gún nínú odó.
3). Ti isu ba ti jiná, l’ẹ́hìn ti àti fọ odó àti ọmọ odó, a o kó iṣu náà si odó, a wa fi ọmọ odó gún dára dára títí yoo fi kómọra, ti o ba le, a lè fi omi gbọna díẹ̀ si láti jẹ ko rọ̀ ki o lè ṣe jẹ.
4). Ti o ba ti tẹ́ wa lọ́rùn, oúnjẹ ti de ‘le ní yẹn o, a o bu si àwo, pẹ̀lú obẹ̀, iṣe ya! Njẹ ẹnu rẹ̀ nda ‘tọ̀?

Ìtọ́ka sí ìparí – Iṣu paradà o di iyán »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Oúnjẹ ilẹ̀ wa

láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ọbẹ̀ ẹ̀fọ́Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yìí.
Ṣe àláfià lẹ̀ wa, àwọn ará ilé nkọ́?

Ni ọ̀sẹ̀ yìí a máa wo oríriṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ wa.
Oúnjẹ l’ọrẹ awọ, oúnjẹ to dára ṣe pàtàkì gan ní.

Ní ilẹ̀ Yorùbá, ọbẹ̀ àti òkèlè wọ́pọ̀ nínú oúnjẹ ti a máa jẹ́.
Oríriṣiríṣi ọbẹ̀ lo wa gẹ́gẹ́bí ẹ̀fọ́ rirọ, ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀, amunu, tutù, arowójẹja,
ilá funfun, ilá asẹpọ, omi ọbẹ̀, ọbẹ̀ fún iba, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Iyán, ẹ̀bà àti àmàlà ní àwọn oúnjẹ òkèlè to wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Oúnjẹ wo ní ẹ fẹ́ràn jù?

Ìtọ́ka sí ìparí – Oúnjẹ ilẹ̀ wa »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Àṣà ìlà kíkọ si ojú

láti ọwọ́ Ajialàrà.

Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yìí.
Gẹ́gẹbi a ti sọ ni ọ̀sẹ̀ to kọjá, àṣà kikọ ìlà si ojú jẹ́ ikan lara àwọn ohùn ti àwọn ìyá wa máa fi bùkún ẹwa ojú wọn ní ayé àtijọ́. Ṣùgbọ́n ko wọpọ mọ nítorí ìdí mẹ́ta:
- Akọ́kọ́, nítorí ọlaju: àwọn obìnrin ayé òde òní ri kikọ ìlà si ojú bi ohun ìbílẹ̀.
- Ìdí kéjì ní ìtìjú, nítorí yẹ́yẹ́ àti àpárá, gẹ́gẹbi ibéèrè báyi “ṣe ẹ ba kìnìún jà ní?”
- Ìdí kẹ́ta, ní òfin ti ìjọba gbé jáde ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ní ọdún 2006 àti ní ìpínlẹ̀ Ọsùn ni ọdún 2009 nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé.
Èyí jẹ́ ohun ti o jẹ ki ogunlọ́jọ̀ ìdílé pa àṣà yi rẹ.

Ní ayé atijọ, àwọn àgbèègbè àti ìlú máa kọ oríṣiríṣi ìlà ti wọn fi da ara wọn mọ̀. Bi àwọn ti a mọ̀ si Ọ̀yọ̀ l’oni, ti ni oríṣiríṣi ìlà ti wọn fi da ara mọ, ni àwọn Ẹ̀gbá, Ìjẹbú, Ifẹ̀, Oǹdó, Ijẹ̀ṣá, Èkìtì àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ náà ni oríṣi ìlà ti wọn fún ọmọ ti wọn bá bi. Ẹ tẹ̀ ibi ti atọ́ka si, ni ìsàlẹ̀ yìí, láti rí afihàn àwọn aworan díẹ̀, ninu awọn oríṣiríṣi ìlà ti wọn kọ ni ilẹ̀ Yorùbá.
Ìtọ́ka sí ìparí – Àṣà ìlà kíkọ si ojú »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Oge Ojú

láti ọwọ́ Ajialàrà.

Ẹ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yii.

Ni ọ̀sẹ̀ yii a máa wo oríriṣiríṣi nkan ti àwa obìnrin máa nlo ní àtijọ́ àti ode ìwòyí láti fi ṣe ojú wa l’eṣọ́.
Ní àtijọ́, ìla kikọ jẹ́ ohun ti o gbajúmọ̀ gaan ni láàrín àwọn obìnrin, (nítorí ìdí èyí ní ọ̀sẹ̀ ti o mbọ mo máa sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi ìla kikọ) ṣùgbọ́n nínú ọ̀rọ̀ mi lòní mo máa sọ̀rọ̀ nípa ohun míràn ti àwọn ìyá wa máa nlo ní àtijọ́ bi tìróò, osun, laalì, mọju àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ.
Ní ayé àtijọ́ àwọn obinrin wa máa kun tìróò yika ojú won láti fi gbé ẹwà ojú wọn jáde gẹ́gẹ́bí àwọn obìnrin ode ìwoyí ṣe lo nkan ti a npe ní “eye pencil” ní èdè Gẹ̀ẹ́si.

Ìtọ́ka sí ìparí – Oge Ojú »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Fìwàṣayé

láti ọwọ́ Ajialàrà.

IwaẸ kábọ̀ si Ayé Obìnrin ti ọ̀sẹ̀ yi.

Mo sọ ní ọ̀sẹ̀ ti o kọjá pe a o máa wo oríṣiríṣi nkan ti obìnrin ìwòyí àti ti àtijọ́ máa nlo láti jẹ ki ojú wa gun régé ṣùgbọ́n ki a to wo àwọn ohun wọ̀nyi, mo fẹ sọ̀rọ̀ ní ṣoki nípa ÌWÀ. Bi ẹ ṣe mọ̀ wípe ìwà lẹwà, wọn ní obìnrin sọ ìwà nù, ko ri ilé ọkọ gbe.

Mo fẹ́ rọ̀ yin ẹ yin obìnrin ẹgbẹ́ mi àti gbogbo ènìyàn ti nkà Ọrọ̀ yi wípe ki a fi ìwà ti o dára ṣayé.
Ẹ ba mi kalọ pẹ̀lú ewì (ìsàlẹ̀ yi).

Ìtọ́ka sí ìparí – Fìwàṣayé »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Irun dídì àti kikó

láti ọwọ́ Ajialàrà.

Irun dídì àti Kikó ní àṣà Yorùbá jẹ́ lara ohún ti máa bùkún ẹwà fùn Obìnrin wa.
Bi a ba kọ́kọ́ ri obìnrin, irun orí jẹ́ ohùn ti a o wo, bóyá o dára tàbí ko dára.
A máa wo oríṣiríṣi irun dídì and kikó ti àtijọ́ àti ti òde ìwòyí.
Ipakọ Ẹlẹdẹ Ṣuku

 

 

 

 

 

 

Báwo ní a nṣe dí irun tàbí kó irun?
Ẹní ti o ba dí irun tàbí kó irun ní a pé ní “Onídìrí”
Onídírì yi o dí irun tàbí kó irun bi o ba ṣe fẹ́
tàbí ki o fi àwọn àwòrán irun dídì ati kikó hàn ẹ, ki o mú iru eyi to wu ẹ.
Ni ṣoki, ti o ba fẹ dì irun tàbí kó irun rẹ̀ , onídírì yi o la irun náà , ko to bẹ̀rẹ̀ iṣẹ kikó tabi dídì.
Eyi ni diẹ ninu irun ayé atijọ

 Kẹhin s'ọkọOnile Gogoro

 

 

 

 

 

 

 

 

Ìtọ́ka sí ìparí – Irun dídì àti kikó »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ìyá ní wúrà

Black_mother_and_daughter_800x532láti ọwọ́ Ajialàrà.
Ẹ kú dédé àsìkò yi o.
Ẹ kábọ̀ si “Ayé Obìnrin“.
Ní ọ̀sẹ̀ yii, a o wo ipò Obìnrin gẹ́gẹbi Ìyá.

Bí wọn ti máa ńsọ wí pe:
“Ìyá ní wúrà”, àti wí pe “òrìṣà bi Ìyá o si”,
bẹ́ẹ̀ni o, òrìṣà bi Ìyá o si, bi ìyá abiyamọ tọ̀ọ́tọ́.
Ìyá ní o bí gbogbo wa,
Ìyá ni olùtọ́jú wa,
ipò Ìyá ko ṣe fi ọwọ́ rọ sẹ̀hìn rárá.
Gẹ́gẹ́bí orin àtijọ́ kan ṣe lọ báyi wí pe:
Ìyá ní wúrà iyebíye
Ti a ko le f’owó ra
O l’oyún mi fún oṣù mẹsan
O pọ̀n mi f’ọdún mẹ́ta
Ìyá ní wúrà iyebíye
Ti a ko le f’owó ra

Ha Ìyá, ohun ẹlẹgẹ́ ní o!
Ìyá ṣe pàtàkì ní àṣà ilẹ wa, ẹ rántí ilé.
Ẹ jẹ́ ka rántí ìyá ti o ṣe ọlọkọ̀ wa s’ayé.
Ẹ jẹ́ ka bu ọ̀wọ̀ àti iyì fún Ìyá wa.
Ìyá mi, wa pẹ l’ayé, Ìyá mi o, wa jèrè ọmọ.
Ìyá mi, abiyamọ tọ̀ọ́tọ́.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ìyá ní wúrà »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ayé Obìnrin (ọ̀rọ̀ àsọṣaájú)

láti ọwọ́ Ajialàrà
Irú ìgbésí ayé wo ní Obìnrin wà?
Obìnrin ní ìyá wá, olùrànlọ́wọ́, alábarò, ọ̀rẹ́, àbúrò, ẹ̀gbọ́n àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Wo àyíká rẹ̀ ki o sọ fún mi ipò ti obìnrin wá nínú ayé rẹ̀?
ObinrinLiberian PresidentObama women - White House
Gẹ́gẹbi Obìnrin, a o maa wo ní ìpele ní ìpele gbogbo nkan ti Obìnrin fi jẹ́ Obìnrin.
Ní ọ̀sẹ̀ to ḿbọ̀, a o sọ̀rọ̀ nípa Obìnrin gẹ́gẹ́bi Ìyá wà.
Ẹ kábọ̀ o, si “Ayé Obìnrin“.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ayé Obìnrin (ọ̀rọ̀ àsọṣaájú) »
Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter