Oríkì ko pín si orúkọ tàbí ìdílé nikan.
Bi a ti nkì ènìyàn si orúkọ àti ìdílé, bẹ́ẹ̀ l’a nkì ènìyàn si ìlú.
Kiki ènìyan si ìlú l’a npe ní orílẹ̀ èyí fi díẹ̀ ṣínnṣín yàtọ̀ si oríkì.
Gbogbo ènìyàn ti a ba bi l’àárín ìlú yìí l’a o kì bákànnáà.
Ko sí ídìlè ti a ko lè kì bẹ́ẹ̀; èyí gaan ní i jẹ orílẹ̀.
Fún àpẹ̀rẹ̀ ẹni a bi ní Ìkọ̀lé Èkìtì l’a nki pe: Ọmọ Ẹlẹ́kọ̀lè Ọ̀balaya-aṣọ. Ọmọ Ìkọ̀lé ko rì nkan f’aṣọ ṣe, nwọn da àlà bo’ṣè.
Oǹdó: Ọmọ Èkí mọ̀jú Ọmọ Akín.
Òṣogbo: Órokì Ọmọ Ọ̀ṣun.
Ilọrọ Èkìtì: Ọmọ èjì ọrọ, Ọ́rọ̀gọ̀dọ̀ ti njẹ ìgbín, Ọmọ amú’dà silẹ-f’ogun ẹnu pa’ni.
Ikoro Èkìtì: Ọmọ ẹ̀ṣọ̀-ọ̀bẹ̀, Ọmọ amù’dà p’ariko.
Ìtọ́ka sí ìparí – Orílẹ̀ »
Oríkì jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí ti àwọn Yorùbá máa nfi yin ará wọn tàbí ẹni ti inú wọn ba dùn si. Àṣà yìí ní a fi ndá ènìyàn l’ará yá fún ohun rere ti o ṣe tàbí láti fihàn ènìyàn nígbàmíràn pe inú wa dùn si olúwarẹ̀. Bi ènìyàn ba nṣe iṣẹ́ tàbí o njó l’ojú agbo, bi o ba gbọ́ oríkì rẹ̀, ará rẹ̀ a ya gágá a si mura so ohun ti o ba nṣe nígbànáà dáradára.
Oríṣiríṣi ọ̀nà l’a nki ènìyàn si. Bi a ti nki Ọba bẹ́ẹ̀ la nki mẹ̀kùnnù pẹ́lu. A si tún lè ki ènìyàn si ìdilé ibi ti a bi, bàkannáà a nki ènìyàn si orúkọ rẹ̀, paápàá orúkọ àmútọ̀runwa, àpẹẹrẹ ní àwọn bi Àjàyí àti Dàda.
Ìtọ́ka sí ìparí – Oríkì »
Àjàyí la nki bayi pe:-

Àjàyí, ògídíolú,
Òlóló, oníkànga àjípọn,
Òbomi òṣùùrù wẹdà.
Ẹkùn baba ọdẹ
Ẹkùn pakọ̀rọ̀ wolẹ̀.
Ẹni Àjàyí gbà gbà gbà,
Ti ò le gbà tan, Igúnnugún ní í gba oluwarẹ.
Àjàyí ti nwẹ lódò,
Ìtọ́ka sí ìparí – Àjàyí (Oríkì Orúkọ àmútọ̀runwa) »
Àṣáró, arẹ-dòdò ẹwà,
À-rí-má-leè-lọ, à-wò-padà-sẹhìn.
Kòì d’ẹ́nu à nd’ọ́fun tòló.
A-jí-má-tì-í, arẹwà nínú ìkòkò;
Afinjú onjẹ tí í f’epo wẹ ‘ra.
Ìtọ́ka sí ìparí – Àṣáró »

Obì
Oriṣi obì meji l’ó wà:
Obì gidi, eyi ni àdáyébá,
a máa l’áwẹ́ mẹta si mẹfa,
ọdun keje si ẹkẹjọ ni sii saaba wọ ilé èso.
Awọn Ìjẹ̀ṣà si fẹran à ti máa gbin obì,
wọn si gbà pé, igi owó ($ £ ₦) ati igi ọrọ̀
ni ó jẹ́ fún awọn.
Eyi ni ó mú ki á máa ki Ìjẹ̀ṣà bayii:
Ìjẹ̀ṣà ó sun ore,
Ọmọ onilé obi,
Ìjẹ̀ṣà o sun ore,
Ọmọ olóbì wọ́ọ́wọ́ntiwọ́,
Ọmọ olóbì wọ̀ọ̀wọ̀ntiwọ̀,
Ọmọ Ìjẹ̀ṣà ti yoo bá ọrọ̀ kú,
Bí o bá fún unn l’óbì kan ṣoṣo
A máa so l’ábo l’ábo.
Eyi ti yoo bá òṣì ku,
Bi o báfún un l’óbì kan. A máa so l’akọ l’ákọ.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìjẹ̀ṣà àti Obì »

Dàda, aládé orí jinbíti
Onímọ̀galà
Ẹran gbígbẹ ò níjàǹjá.
Dàda kò lè já
Ó làbúrò tó gbójú,
Ta làbúrò Dàda?
Ọya òrííriì
Ẹkùn àṣèké.
Ìṣẹ owó kì í ṣẹ Dàda,
Dàda olówó-ẹyọ
Èsì àwọn ènìyàn
09/02/2010 (7:53) Mark Twain pa òwe Yorùbá méjì
08/30/2010 (12:06) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
08/07/2010 (11:08) Ta ló mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí?
07/03/2010 (11:58) Traducción de Español a Yoruba
07/02/2010 (6:19) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/23/2010 (6:06) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Njẹ́ o yẹ ki ọkùnrin máa dí irun bi?
06/21/2010 (1:45) Idamu Alárinà : Kíni ki nṣe? (Apá kẹ́ta)
06/18/2010 (9:56) Ìdíje bọ́ọ̀lù afẹsẹ̀gbá àgbáyé
06/08/2010 (10:41) Ẹ dá sọ̀rọ̀ yìí : Òfin ìjọba nípa àṣà kikọ ìlà si ojú ọmọdé?
06/06/2010 (10:49) Ẹ̀wà: Oúnjẹ ìbéjì