Ọ̀yọ́túnjí - Ìlú Yorùbá ní Amẹ́ríkà

Ọ̀yọ́túnjí jẹ́ ìlú tí àwọn ènìyàn aláwọ̀-dúdú ti o jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà  
dásílẹ̀ ní ọdún 1970, láti gbé àṣà àti eṣìn ìbílẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá larugẹ ní Amẹ́ríkà.
Ìlú Ọ̀yọ́túnjí wà ní ìpínlẹ̀ South Carolina ní gúúsú orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ọ̀yọ́túnjí: ìlú Yorùbá ní Amẹ́ríkà »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Orílẹ̀

Fru_DohOríkì ko pín si orúkọ tàbí ìdílé nikan.
Bi a ti nkì ènìyàn si orúkọ àti ìdílé, bẹ́ẹ̀ l’a nkì ènìyàn si ìlú.
Kiki ènìyan si ìlú l’a npe ní orílẹ̀ èyí fi díẹ̀ ṣínnṣín yàtọ̀ si oríkì.
Gbogbo ènìyàn ti a ba bi l’àárín ìlú yìí l’a o kì bákànnáà.
Ko sí ídìlè ti a ko lè kì bẹ́ẹ̀; èyí gaan ní i jẹ orílẹ̀.

Fún àpẹ̀rẹ̀ ẹni a bi ní Ìkọ̀lé Èkìtì l’a nki pe: Ọmọ Ẹlẹ́kọ̀lè Ọ̀balaya-aṣọ. Ọmọ Ìkọ̀lé ko rì nkan f’aṣọ ṣe, nwọn da àlà bo’ṣè.
Oǹdó: Ọmọ Èkí mọ̀jú Ọmọ Akín.
Òṣogbo: Órokì Ọmọ Ọ̀ṣun.
Ilọrọ Èkìtì: Ọmọ èjì ọrọ, Ọ́rọ̀gọ̀dọ̀ ti njẹ ìgbín, Ọmọ amú’dà silẹ-f’ogun ẹnu pa’ni.
Ikoro Èkìtì: Ọmọ ẹ̀ṣọ̀-ọ̀bẹ̀, Ọmọ amù’dà p’ariko.
Ìtọ́ka sí ìparí – Orílẹ̀ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Afihàn èré atijọ́ láti Ilé-Ifẹ̀ ní ìlú London

Ilé àkójọpọ̀ ohun àtata àti ohun láílai ní orílẹ̀-èdè UK (èyí ti a npe ní “British Museum” ní èdè Gẹ̀ẹ́si) ti bẹ̀rẹ̀ afihàn àwọn èré àtijọ́ láti Ilé-Ifẹ̀, lení ọjọ́ kẹ̀rin oṣù kẹ́ta ọdún 2010. Ni ìsàlẹ̀ ọ̀rọ̀ yi, a fi itọ́ka si ayélújára níbíti ẹ ti le ri ẹ̀kúnrẹrẹ àlàyé nípa afihàn yi, ní ìlú London.
Itọ́ka

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ìjẹ̀ṣà àti Obì

Obi

Obì

Oriṣi obì meji l’ó wà:
Obì gidi, eyi ni àdáyébá,
a máa l’áwẹ́ mẹta si mẹfa,
ọdun keje si ẹkẹjọ ni sii saaba wọ ilé èso.

Awọn Ìjẹ̀ṣà si fẹran à ti máa gbin obì,
wọn si gbà pé, igi owó ($ £ ₦) ati igi ọrọ̀
ni ó jẹ́ fún awọn.

Eyi ni ó mú ki á máa ki Ìjẹ̀ṣà bayii:
Ìjẹ̀ṣà ó sun ore,
Ọmọ onilé obi,
Ìjẹ̀ṣà o sun ore,
Ọmọ olóbì wọ́ọ́wọ́ntiwọ́,
Ọmọ olóbì wọ̀ọ̀wọ̀ntiwọ̀,
Ọmọ Ìjẹ̀ṣà ti yoo bá ọrọ̀ kú,
Bí o bá fún unn l’óbì kan ṣoṣo
A máa so l’ábo l’ábo.
Eyi ti yoo bá òṣì ku,
Bi o báfún un l’óbì kan. A máa so l’akọ l’ákọ.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìjẹ̀ṣà àti Obì »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ilé-Ifẹ̀

Ilé-Ifẹ̀ jẹ́ ìlú t’ó ṣe pàtàkì púpọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Ìtàn sọ wípé Yorùbá bẹ̀rẹ̀ láti Ilé-Ifẹ̀.
Odùduwà l’ẹni tí ó ṣẹ Yorùbá sílẹ.
Ifẹ̀ jẹ́ ìlú t’ó tóbi.
Ọpọlọpọ̀ ère l’ó wà ní Ilé-Ifẹ̀.
Ọpá Ọrányàn jẹ ohun t’ó ṣe pàtàkì ní Ilé-Ifẹ̀.
Odùduwà t’ó ṣẹ Yorùbá sílẹ̀ jẹ enìà tí o ṣe pàtàkì.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ilé-Ifẹ̀ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ìbàdàn

Ìbàdàn jẹ́ olú ilú fun ìjọba ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Òjò a maa rọ̀ púpọ̀ n’Íbàdàn.
L’ásìkò ẹ̀rùn n’Íbàdàn, oòrún a maa mú púpọ̀.
Ibadàn jẹ́ nkan lara àwọn ìlú t’ó tóbi ni ilẹ̀ Afíríkà.
Ìbàdàn ni ohun tí o pọ̀ ju Èkó lọ nínú iṣẹ́ ọwọ́.
Ìbàdàn tóbi púpọ̀ ju àwọn ìlú yokù lọ.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ìbàdàn »
Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ògbómọ̀ṣọ́

Ògbómọ̀ṣọ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìlú ti ó tóbi ní ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn ìlú tí ó yí Ògbomọ̀ṣọ́ ká ni Ọ̀yọ́, Ilọ́rin àti Èjigbò.
Ògbómọ̀ṣọ́ tọ́ bí máílì mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n sí Ọ̀yọ́.
Àwọn oníṣẹ́ Ọlọ́run pọ̀ púpọ̀ níbẹ̀.
Àwọn tí ó wà níbẹ̀ ní ìjọ Baptísì.
Nwọ́n kọ́ sọsì tí ó tóbi, nwọ́n si ní ilé iwé ti o pọ̀ púpọ̀ ni Ògbómọ̀ṣọ́.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ògbómọ̀ṣọ́ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

Ìlú Ọ̀yọ́

 

Ọ̀yọ́ jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn ìlú tí ó wà yíká Ọ̀yọ ní Áwẹ́, Akínmọrìn, Fìditì àtí Ṣakí.
Àwọn oníṣẹ́ ọwọ pọ̀ púpọ̀ ní Ọ̀yọ́.
Ṣàngo ni ọba tí ó ṣe pàtàkì ní Ọ̀yọ́.

Ìtọ́ka sí ìparí – Ìlú Ọ̀yọ́ »

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter

ÌLÚ ABẸ́ÒKÚTA

Olumọláti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)

Abẹ́òkúta ìlú Ẹ̀gbá, ìlú Ẹ̀gbá Aké, ìlú Ẹ̀gbá Òwu, ìlú Ẹ̀gbá Òkè-Ọnà, ìlú Ẹ̀gbá Àgùrà, ìlú Ẹ̀gbá Ìbarà, ìlú Líṣàbi-Agbòǹgbò-àkàlà, ìlú Lámodi, ìlú Ajíbóyèdé, ìlú Ṣodẹkẹ́-ọmọ Ẹfúwọ̀ ìlú Olúmọ, ìlú abẹ́ òkúta. Abẹ́òkúta ìlú Ẹ̀gbá.

 

Pín káàkiri:
  • Facebook
  • Twitter