
Obì
Oriṣi obì meji l’ó wà:
Obì gidi, eyi ni àdáyébá,
a máa l’áwẹ́ mẹta si mẹfa,
ọdun keje si ẹkẹjọ ni sii saaba wọ ilé èso.
Awọn Ìjẹ̀ṣà si fẹran à ti máa gbin obì,
wọn si gbà pé, igi owó ($ £ ₦) ati igi ọrọ̀
ni ó jẹ́ fún awọn.
Eyi ni ó mú ki á máa ki Ìjẹ̀ṣà bayii:
Ìjẹ̀ṣà ó sun ore,
Ọmọ onilé obi,
Ìjẹ̀ṣà o sun ore,
Ọmọ olóbì wọ́ọ́wọ́ntiwọ́,
Ọmọ olóbì wọ̀ọ̀wọ̀ntiwọ̀,
Ọmọ Ìjẹ̀ṣà ti yoo bá ọrọ̀ kú,
Bí o bá fún unn l’óbì kan ṣoṣo
A máa so l’ábo l’ábo.
Eyi ti yoo bá òṣì ku,
Bi o báfún un l’óbì kan. A máa so l’akọ l’ákọ.
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìjẹ̀ṣà àti Obì »

Inu didun nii mú araáya-wá,
ẹni ti inu rẹ̀ bá si dùn, ti ara rẹ̀ yá,
yoo yọ̀, yoo si jó, bayii ni awọn baba wa ṣe bẹrẹ iṣẹ́ ìlù,
nigba ti ó yá, ó di wi pe ọpọlọpọ nńkan ṣiṣe ni à ń lo ìlú fún,
ìlú si di iṣẹ idile awọn ẹbi kan. Irú awọn ẹbi wọnyi ni ń jẹ orukọ
bii Àyándélé, Onílúdé, Onígbìndé ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Eyi ni diẹ ninu awọn ohun ti à ń fi ìlù ṣe:
(i) Fún idárayá ni ibi ìnáwó,
ìbáà ṣe ìgbeyàwó, ìnáwó ọdun titun, ìkómọjáde,
òkú egbodo ati ijó ẹgbẹ́ ati oriṣiriṣi àríyá;
(ii) Lati ji ọba l’ori ìtẹ́;
(iii) Fún ìyẹ́sí àlejó àtàtà;
(iv) Bi ohun èlò ìranlọwọ nigba ogun.
Láyé atijo, bi ìletò kò bá jìn si ara wọn,
awọn ara ìletò kìíní lè fi ìlù ṣòfófó fún ti ekeji pe ogun dé.

Ìkíni jẹ́ àṣà pàtàkì ninú àwọn àṣà Yorùbá.
Èyí ni díẹ̀ ninú ìkíni fún àkànṣe àti oríṣiriṣi àsikò ní ilẹ̀ Yorùbá:-
1.) Ẹni tí ó bímọ:-
(a) Mo yọ̀ fún ọ
(b) Ayọ̀ abara tintin
(d) Ẹ kú ewu ọmọ
(e) Bárikà tí a gbọ́ ohùn iyá àti ọmọ
Ìdáhùn - Ayọ̀ yóò kárí o!
2). Ẹni tí ó ń gbéyàwó
(a) Ẹhin ìyàwó kò ní mọ ẹni
Ìdáhùn -Àwa nùun
(b) Wòyi oṣu mẹsàn-án ìlasa ọmọ ni a ó máa jẹ
Ìdáhùn – Aṣẹ o!
(d) Ẹ kú ọwọ l’ómi
(e) Ẹ kú láàsigbò
(ẹ) Òwò èrè ni Olúwa yóò é o
3). Fún ìdágbére:-
Ìpàdé wa bii oyin
Ọlọ́run má kọ àtúnrí
Ọlọ́run kò ní i ṣe èyi i’árìmọ
Ìdáhùn:
Àṣẹ, Ọlọrun yọ́ọ̀ dá ẹ̀mí wa sí
4). Ní ìgbà òtútú – Ẹ kú òtútú yìí
Ìdáhùn – Kò sí bí ò ti ri !
5). Ní àsìkò ọdún :-
(a) Ẹ kú ọdún
(b) Ẹ kú ìyèdún
(d) Ọdún ó ya abo
(e) Ẹ̀mí yóò rí òpin ọdún
Ìdáhùn - Àmín
Ìtọ́ka sí ìparí – Ìkíni (Yorùbá) fún àkànṣe àti oríṣiriṣi àsikò »
Ìtọ́ka sí ayélújára ní èdè Faransé (Français) ńibí ti wọn ti tò lẹ́sẹẹsẹ oríṣiríṣi ìkíni Yorùbá to le ní igba (200), ti wọn lo ní orílẹ̀-èdè Bẹ̀nẹ̀n (Benin) nílẹ̀ Idàhọ̀mi :-
http://www.beninensis.net/Salutations_Yoruba.htm

láti ọwọ́ Akéwìjesu (Ọ̀gbẹ́ni Adélékè Ọṣìndẹ́kọ ní ìlú Ìbàdàn)
Bójúmọ́ báti mọ́, ẹ̀ jí ire bí ni à ńkí ara ẹni.
Bọ́mọdé bá rágbà wọn à kìwọn pé kẹ́ẹpẹ́ baba.
Onídírì làńkí pé – Ojú gbooro.
Wọ́n á dáhùn pé – Òyà yíó yà.
Alágbẹ̀dẹ – Àrọyè o.
Ìdáhùn – Ògún á gbè ọ́.
Àgbẹ̀ - Àroko bá ọdún dé. Aláró – Àrẹdú.
Ìdáhùn – Ìyá Màpó á gbè ọ́.
Akọ̀pẹ - Ìgbà á rọ́ o. Ọdẹ – Àrìǹpa tògún.
Ìdáhùn – Ògún á gbè ọ́.
Afíńgbá - Ẹ kú ẹ̀rọ̀ ògún.
Ìdáhùn – Onírèse á gbè ọ́. Ìtọ́ka sí ìparí – ÌKÍNI NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ »